2 Kings 13:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn OLUWA ṣàánú fún wọn, ó sì yipada sí wọn nítorí majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; kò sì gbàgbé àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si ṣe oju rere si wọn, o si ṣãnu fun wọn, o si ṣe akiyesi wọn, nitoriti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, kò si fẹ run wọn, bẹ̃ni kò si ta wọn nù kuro niwaju rẹ̀ titi di isisiyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n OLÚWA ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.