2 Kings 13:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jehoaṣi ọba, ọmọ Jehoahasi, ṣẹgun Benhadadi ní ìgbà mẹta, ó sì gba àwọn ìlú tí wọ́n ti gbà ní ìgbà ayé Jehoahasi, baba rẹ̀ pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi si tun gbà ilu wọnni pada lọwọ Benhadadi ọmọ Hasaeli, ti o ti fi ogun gbà lọwọ Jehoahasi baba rẹ̀. Igba mẹta ni Joaṣi ṣẹgun rẹ̀, o si gbà awọn ilu Israeli pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì gbà padà kúrò lọ́wọ́ Bẹni-Hádádì ọmọ Hásáélì àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jéhóáhásì. Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta, Jéhóásì ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà.