2 Kings 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jehoahasi kò ní àwọn ọmọ ogun mọ́ àfi aadọta ẹlẹ́ṣin, ati kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́wàá ati ẹgbaarun (10,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ọba Siria ti pa gbogbo wọn run, ó lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi erùpẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni kò kù ninu awọn enia fun Jehoahasi, bikòṣe ãdọta ẹlẹṣin, ati kẹkẹ́ mẹwa, ati ẹgbãrin ẹlẹsẹ̀; nitoriti ọba Siria ti pa wọn run, o si ti lọ̀ wọn mọlẹ bi ẽkuru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ ogun Jéhóáhásì àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, nítorí ọba Ṣíríà ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.