2 Kings 14:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti wù kí ó rí Ámásíà kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì sì dojúkọ ọ́. Òun àti Ámásáyà ọba Júdà kọjú sí ara wọn ní Bẹti-Ṣéméṣì ní Júdà.