2 Kings 14:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoaṣi ọba Israeli si mu Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi ọmọ Ahasiah ni Betṣemeṣi, o si wá si Jerusalemu, o si wó odi Jerusalemu palẹ lati ẹnu bodè Efraimu titi de ẹnu bodè igun, irinwo igbọnwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Ámásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóásì, ọmọ Áhásáyà ní Bẹti-Ṣéméṣì. Nígbà náà, Jéhóásì lọ sí Jérúsálẹ́mù, ó sì lọ wó odi Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Éfúráímù sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ta ẹsẹ̀ bàtà (600).