2 Kings 14:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dì rikiṣi si i ni Jerusalemu: o si salọ si Lakiṣi; ṣugbọn nwọn ranṣẹ tọ̀ ọ ni Lakiṣi, nwọn si pa a nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jérúsálẹ́mù, ó sì sálọ sí Lákísì, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lákísì, wọ́n sì pa á síbẹ̀.