2 Kings 14:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó gba gbogbo ilẹ̀ Israẹli pada láti ẹnubodè Hamati títí dé Òkun Araba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ láti ẹnu wolii rẹ̀, Jona, ọmọ Amitai, ará Gati Heferi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tun mu agbègbe ilẹ Israeli pada lati atiwọ̀ Hamati titi de okun pẹ̀tẹlẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti sọ nipa ọwọ iranṣẹ rẹ̀ Jona woli, ọmọ Amittai, ti Gat-heferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Ísírẹ́lì padà láti Lebo-Hámátì sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jónà ọmọ Ámítaì, wòlíì láti Gátì Héférì.