2 Kings 14:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Oluwa ri ipọnju Israeli pe, o korò gidigidi: nitori kò si ọmọ-ọdọ, tabi omnira tabi olurànlọwọ kan fun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ti rí bí olúkúlùkù yálà ẹrú tàbí òmìnira, ti ń jìyà gidigidi; kò sì sí ẹnìkan tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.