2 Kings 14:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo nǹkan yòókù tí Jeroboamu ṣe, ìwà akọni rẹ̀ lójú ogun ati bí ó ti gba Damasku ati Hamati, tí wọ́n jẹ́ ti Juda tẹ́lẹ̀ rí, fún Israẹli, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iyokù iṣe Jeroboamu ati gbogbo eyiti o ṣe, ati agbara rẹ̀, bi o ti jagun si, ati bi o ti gbà Damasku, ati Hamati, ti iṣe ti Juda, pada fun Israeli, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéróbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn àṣeyọrí ológun rẹ̀ àti bí ó ṣe gbà padà fún Ísírẹ́lì lápapọ̀. Dámásíkù àti Hámátì, tí ó ti jẹ́ ní Yáúdì, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?