2 Kings 14:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò dàbí ti Dafidi baba ńlá rẹ̀; ohun gbogbo tí Joaṣi baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, ṣugbọn kì iṣe bi Dafidi baba rẹ̀: o ṣe gẹgẹ bi ohun gbogbo ti Joaṣi baba rẹ̀ ti ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLÚWA, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dáfídì baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ́lé àpẹrẹ baba a rẹ̀ Jóásì.