2 Kings 14:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Amasaya pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó ṣẹgun Sela, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jokiteeli, orúkọ yìí ni ìlú náà ń jẹ́ títí di òní yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On pa ẹgbãrun ninu awọn ara Edomu ni afonifojì iyọ, o si fi ogun kó Sela, o si pè orukọ rẹ̀ ni Jokteeli titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ará Édómù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ iyọ̀, ó sì fi agbára mú Ṣélà nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jókítélì, orúkọ tí ó ní títí di òní.