2 Kings 15:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Menahemu si fi agbara gbà owo na lọwọ Israeli, ani lọwọ gbogbo awọn ọlọrọ̀, ãdọta ṣekeli fadakà lọwọ olukuluku enia, lati fi fun ọba Assiria. Bẹ̃ni ọba Assiria yipada, kò si duro ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ménáhémù fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Áṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Áṣíríà padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.