2 Kings 15:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Peka, ọmọ Remalaya, olórí ogun rẹ̀, pẹlu aadọta ọmọ ogun Gileadi dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní Samaria, ninu ilé tí a mọ odi tí ó lágbára yíká, tí ó wà ninu ààfin rẹ̀, Peka sì jọba dípò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Peka ọmọ Remaliah, olori-ogun rẹ̀, dì rikiṣi si i, o si kọlù u ni Samaria, li odi ile ọba, pẹlu Argobu, ati Arie, ati ãdọta enia ninu awọn ọmọ Gileadi pẹlu rẹ̀: o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.