2 Kings 15:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò tí Peka jọba Israẹli ni Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gba ìlú Ijoni, Abeli Beti Maaka, Janoa, Kedeṣi, Hasori, ati ilẹ̀ Gileadi, Galili ati gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lẹ́rú lọ sí Asiria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà Pékà ọba Ísírẹ́lì, Tígílátì Pílésérì ọba Ásíríà wá, ó sì mú Íjónì, Abeli-Bẹti-Máákà, Jánóà, Kédéṣì àti Hásórì. Ó gba Gíléádì àti Gálílì pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Náftalì. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Ásíríyà.