2 Kings 15:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. On kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn tẹ̀ṣíwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jótamù tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún OLÚWA ṣe.