2 Kings 15:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA sọ Asaraya ọba di adẹ́tẹ̀, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó ń dá gbé. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì ń ṣàkóso ìjọba nípò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si kọlù ọba na, bẹ̃li o di adẹtẹ̀ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile ihámọ: Jotamu ọmọ ọba si wà lori ile na, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jótamì, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.