2 Kings 15:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ṣe ohun burúkú níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe. Ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu; ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi awọn baba rẹ̀ ti ṣe: on kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ṣe búburú lójú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá.