2 Kings 16:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Ahasi lọ pàdé Tigilati Pileseri ọba, ní Damasku, ó rí pẹpẹ ìrúbọ kan níbẹ̀, ó sì ranṣẹ sí Uraya alufaa pé kí ó mọ irú rẹ̀ gan-an láìsí ìyàtọ̀ kankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahasi ọba si lọ si Damasku lati pade Tiglat-pileseri, ọba Assiria, o si ri pẹpẹ kan ti o wà ni Damasku: Ahasi ọba si rán awòran pẹpẹ na, ati apẹrẹ rẹ̀ si Urijah alufa, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ ọnà rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì lọ sí Dámásíkù láti pàdé Tigilati-Pílésérì, ọba Ásíríà, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Dámásíkù: Áhásì ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Úráyà àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.