2 Kings 16:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ki Ahasi tó dé, Uraya bá mọ irú pẹpẹ ìrúbọ náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ahasi rán sí i láti Damasku.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Urijah alufa si ṣe pẹpẹ kan gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba fi ranṣẹ si i lati Damasku wá; bẹ̃ni Urijah alufa ṣe e de atibọ̀ Ahasi ọba lati Damasku wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Úráyà àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Áhásì ọba fi ránṣẹ́ síi láti Dámásíkù; bẹ́ẹ̀ ni Úráyà àlùfàá ṣe é dé ìpadàbọ̀ Áhásì ọba láti Dámásíkù.