2 Kings 16:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún Uraya alufaa, ó ní, “Máa lo pẹpẹ ìrúbọ tí ó tóbi yìí fún ẹbọ sísun àárọ̀ ati ẹbọ ohun jíjẹ ìrọ̀lẹ́, ati fún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ti ọba, ati fún ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu ti àwọn eniyan. Kí o sì máa da ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n bá pa fún ìrúbọ sí orí rẹ̀. Ṣugbọn gbé pẹpẹ ìrúbọ idẹ tọ̀hún sọ́tọ̀ fún mi kí n lè máa lò ó láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahasi ọba si paṣẹ fun Urijah alufa, wipe, Lori pẹpẹ nla ni ki o mã sun ọrẹ-sisun orowurọ̀ ati ọrẹ-jijẹ alalẹ, ati ẹbọ-sisun ti ọba, ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, pẹlu ọrẹ-sisun ti gbogbo awọn enia ilẹ na, ati ọrẹ-jijẹ wọn, ati ọrẹ ohun-mimu wọn; ki o si wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ ọrẹ-sisun na lori rẹ̀, ati gbogbo ẹ̀jẹ ẹbọ miran: ṣugbọn niti pẹpẹ idẹ na emi o mã gbero ohun ti emi o fi i ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhásì ọba sì pàṣẹ fún Úráyà àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa ṣun ọrẹ-ṣíṣun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jijẹ alaalẹ́, àti ẹbọ ṣíṣun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ ṣíṣun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ọrẹ-sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn: ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.”