2 Kings 16:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ahasi gé àwọn ẹsẹ̀ idẹ ti agbada ńlá, ó gbé agbada náà kúrò. Ó tún gbé agbada omi ńlá tí a fi idẹ ṣe, tí wọ́n gbé ka ẹ̀yìn àwọn akọ mààlúù idẹ mejila, ó sì gbé e lé orí ìpìlẹ̀ tí a fi òkúta ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahasi ọba si ké alafo ọnà arin awọn ijoko na, o si ṣi agbada na kuro lara wọn; o si gbé agbada-nla na kalẹ kuro lara awọn malu idẹ ti mbẹ labẹ rẹ̀, o si gbé e kà ilẹ ti a fi okuta tẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhásì ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó sí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada nlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́.