2 Kings 16:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé Ahasi fẹ́ tẹ́ ọba Asiria lọ́rùn, ó gbé pátákó tí wọ́n tẹ́ fún ìtẹ́ ọba kúrò, ó sì sọ ibẹ̀ dí ẹnu ọ̀nà tí ọba ń gbà wọ ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibi ãbò fun ọjọ isimi ti a kọ́ ninu ile na, ati ọ̀na ijade si ode ti ọba, ni o yipada kuro ni ile Oluwa nitori ọba Assiria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé OLÚWA nítorí ọba Ásíríà.