2 Kings 16:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò kan náà ni ọba Edomu gba Elati pada, ó sì lé àwọn ará Juda tí wọn ń gbé ibẹ̀, àwọn ará Edomu sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akokò na, Resini ọba Siria gbà Elati pada fun Siria, o si lé awọn enia Juda kuro ni Elati: awọn ara Siria si wá si Elati, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà, Résínì Ọba Ṣíríà gba Élátì padà fún Ṣíríà, ó sì lé àwọn ènìyàn Júdà kúrò ní Élátì: àwọn ará Ṣíríà sì wá sí Élíátì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.