2 Kings 17:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń sun turari ní gbogbo orí òkè, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. Wọ́n mú kí ibinu OLUWA ru pẹlu ìwà burúkú wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nibẹ ni nwọn si sun turari ni gbogbo ibi giga wọnni, bi awọn keferi ti Oluwa kó lọ niwaju wọn ti ṣe; nwọn si ṣe ohun buburu lati rú ibinu Oluwa soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n ṣun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè tí OLÚWA ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búrubú tí ó rú ìbínú OLÚWA sókè.