2 Kings 17:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kọ ìlànà rẹ̀, wọn kò pa majẹmu tí ó bá àwọn baba ńlá wọn dá mọ́, wọn kò sì fetí sí àwọn ìkìlọ̀ rẹ̀. Wọ́n ń sin oriṣa lásánlàsàn, àwọn pàápàá sì di eniyan lásán. Wọ́n tẹ̀ sí ìwà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká; wọ́n kọ òfin tí OLUWA ṣe fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kọ̀ ilana rẹ̀, ati majẹmu rẹ̀ silẹ, ti o ba awọn baba wọn dá, ati ẹri rẹ̀ ti o jẹ si wọn: nwọn si ntọ̀ ohun asan lẹhin, nwọn si huwa asan, nwọn si ntọ̀ awọn keferi lẹhin ti o yi wọn ka, niti ẹniti Oluwa ti kilọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe ṣe bi awọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀ èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLÚWA ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí OLÚWA ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.