2 Kings 17:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n rú gbogbo òfin OLUWA Ọlọrun wọn; wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meji, wọ́n ń sìn wọ́n. Wọ́n gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, wọ́n sì ń bọ àwọn ohun tí ó wà lójú ọ̀run ati oriṣa Baali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kọ̀ gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, nwọn si ṣe ere didà fun ara wọn, ani, ẹgbọ̀rọ malu meji, nwọn si ṣe ere oriṣa, nwọn si mbọ gbogbo ogun ọrun, nwọn si sìn Baali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n kọ̀ gbogbo òfin OLÚWA Ọlọ́run wọn sílẹ̀ wọ́n sì ṣe òrìṣà méjì fún ara wọn, wọ́n sì gbée sí ọkàn ẹ̀gbọ̀rọ̀ màlúù, àti ère òrìṣà sí ọkàn. Wọ́n sì tẹrí wọn ba sí gbogbo ogun ọ̀run, wọ́n sì sin Báálì.