2 Kings 17:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
títí tí OLUWA fi run wọ́n kúrò níwájú rẹ̀, bí ó ti kìlọ̀ fún wọn láti ẹnu àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Asiria ṣe kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Asiria, níbi tí wọ́n wà títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Titi Oluwa fi mu Israeli kuro niwaju rẹ̀, bi o ti sọ nipa gbogbo awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a kó Israeli kuro ni ilẹ wọn lọ si Assiria, titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Títí tí OLÚWA fi mú wọn kúrò níwájú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ wòlíì. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ wọn lọ sí Iṣánṣà ni Ásíríà.