2 Kings 17:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba Asiria kó àwọn eniyan láti Babiloni, Kuta, Afa, Hamati ati Sefafaimu, ó kó wọn dà sinu àwọn ìlú Samaria dípò àwọn ọmọ Israẹli tí ó kó lọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Samaria, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ìlú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Assiria si kó enia lati Babeli wá, ati lati Kuta, ati lati Afa, ati lati Hamati, ati lati Sefarfaimi, o si fi wọn sinu ilu Samaria wọnni, ni ipò awọn ọmọ Israeli; nwọn si ni Samaria, nwọn si ngbe inu rẹ̀ wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ásíríà mú àwọn ènìyàn láti Bábílónì, Kútà, Áfà, Hámátì àti Ṣéfáfáímù wọ́n sì dúró ní ìlú Ṣamáríà láti rọ́pò àwọn ará Ísírẹ́lì. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.