2 Kings 17:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù OLUWA, nítorí náà OLUWA rán àwọn kinniun sí ààrin wọn, wọ́n sì pa ninu àwọn eniyan tí ọba Asiria kó wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li atètekọ-gbé ibẹ wọn, nwọn kò bẹ̀ru Oluwa: nitorina ni Oluwa ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, ti o pa ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n gbé bẹ́ ẹ ní àkọ́kọ́, wọn kò sì bẹ̀rù OLÚWA, Bẹ́ẹ̀ ni ó rán kìnnìún sí àárin wọn. Wọ́n sì pa nínú wọn.