2 Kings 17:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n bá lọ ròyìn fún ọba Asiria pé àwọn eniyan tí ó kó lọ sí ilẹ̀ Samaria kò mọ òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà, nítorí náà ni Ọlọrun ṣe rán kinniun tí ó ń pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni nwọn ṣe sọ fun ọba Assiria wipe, Awọn orilẹ-ède ti iwọ ṣi kuro, ti o si fi sinu ilu Samaria wọnni, kò mọ̀ iṣe Ọ̀lọrun ilẹ na: nitorina li on ṣe rán awọn kiniun sãrin wọn, si kiyesi i, nwọn pa wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ iṣe Ọlọrun ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sọ fún ọba Ásíríà pé: “Àwọn ènìyàn tí ìwọ lé kúrò tí o sì fi sínú ìlú Ṣamáríà kò mọ ohun tí OLÚWA ìlú náà béèrè. Ó sì ti rán kìnnìún sí àárin wọn, tí ó sì ń pa wọ́n run, nítorí ènìyàn wọn kò mọ ohun tí ó béèrè.”