2 Kings 17:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá pàṣẹ, ó ní, “Ẹ dá ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí a kó lẹ́rú pada sí Samaria, kí ó lè kọ́ àwọn eniyan náà ní òfin Ọlọrun ilẹ̀ náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li ọba Assiria paṣẹ, wipe, Ẹ mu ọkan ninu awọn alufa ti ẹnyin ti kó ti ọhún wá lọ sibẹ; ẹ si jẹ ki wọn ki o lọ igbe ibẹ, ki ẹ si jẹ ki o ma kọ́ wọn ni iṣe Ọlọrun ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ọba Ásíríà pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Ṣamáríà lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí OLÚWA ilẹ̀ náà béèrè.”