2 Kings 17:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí ń gbé Samaria ṣì ń gbẹ́ ère oriṣa wọn, wọ́n fi wọ́n sinu àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọmọ Israẹli ti kọ́. Olukuluku wọn ṣe oriṣa tirẹ̀ sí ibi tí ó ń gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn olukuluku orilẹ-ède ṣe oriṣa tirẹ̀, nwọn si fi wọn sinu ile ibi giga wọnni ti awọn ara Samaria ti ṣe, olukuluku orilẹ-ède ninu ilu ti nwọn ngbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù orílẹ̀ èdè ṣe òrìṣà tirẹ̀ ní gbogbo ìlú níbi tí wọ́n gbé wà, wọ́n sì gbé wọn nínú ilé òrìṣà àti àwọn ènìyàn Ṣamáríà ó sì ṣe wọ́n sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì.