2 Kings 17:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe títí di òní olónìí. Wọn kò bẹ̀rù OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, tabi àṣẹ tí ó pa, tabi òfin tí ó ṣe fún àwọn ọmọ Jakọbu, tí ó sọ ní Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Titi di oni yi nwọn nṣe bi iṣe wọn atijọ: nwọn kò bẹ̀ru Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò ṣe bi idasilẹ wọn, tabi ilàna wọn, tabi ofin ati aṣẹ ti Oluwa pa fun awọn ọmọ Jakobu, ti o sọ ni Israeli;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà náà wá àwọn àlùfáà wọn ṣe bí ti àtẹ̀yìnwá. Wọn kò sin OLÚWA tàbí kí wọ́n fi ara mọ́ ìlànà àti àṣẹ àti òfin tí OLÚWA fi fún ìránṣẹ́ Jákọ́bù, tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.