2 Kings 17:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá wọn dá majẹmu, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, wọn kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, tabi kí wọ́n júbà wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tabi kí wọ́n rúbọ sí wọn;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti Oluwa ti ba dá majẹmu, ti o si ti kilọ fun wọn, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ bẹ̀ru awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ tẹ̀ ara nyin ba fun wọn, tabi ki ẹ sìn wọn, tabi ki ẹ rubọ si wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí OLÚWA ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe sin òrìṣà mìíràn tàbí tẹríba fún wọn, sìn wọ́n tàbí kí ẹ rúbọ sí wọn.