2 Kings 17:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn wọ́n gbọdọ̀ bẹ̀rù OLUWA tí ó mú wọn jáde kúrò ní Ijipti pẹlu ọwọ́ agbára ńlá ati ipá. Ó ní kí wọ́n máa tẹríba fún un, kí wọn sì máa rúbọ sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Oluwa ti o mu nyin gòke ti ilẹ Egipti wá, pẹlu agbara nla ati ninà apá, on ni ki ẹ mã bẹ̀ru, on ni ki ẹ si mã tẹriba fun, on ni ki ẹ sì mã rubọ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n OLÚWA, ẹni tí ó mú yín gòkè jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì pẹ̀lú agbára ńlá àti nínà apá, òun ni ẹni náà tí ó yẹ kí ẹ sìn. Òun ni ẹni tí ó yẹ kí ẹ tẹríba fún àti sí òun ni kí ẹ rúbọ fún.