2 Kings 17:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ní ọdún kan, Hoṣea ranṣẹ sí So, ọba Ijipti pé, kí ó ran òun lọ́wọ́, kò sì san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Asiria mọ́. Nígbà tí Ṣalimaneseri gbọ́, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ju Hoṣea sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Assiria si ri ọ̀tẹ ninu Hoṣea: nitoriti o ti rán onṣẹ sọdọ So ọba Egipti, kò si mu ọrẹ fun ọba Assiria wá bi iti mã iṣe li ọdọdun; nitorina ni ọba Assiria há a mọ, o si dè e ni ile tubu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọba Ásíríà ríi wí pé Hóséà jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán ońsẹ́ sọ́dọ̀ ọba Éjíbítì, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Áṣíríà, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọdún. Nígbà náà ọba Áṣírìa fi agbára mú-ún, ó sì fi sínú túbú.