2 Kings 17:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọdún kẹsan-an tí Hoṣea jọba, ọba Asiria ṣẹgun Samaria, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. Ó kó wọn sí ìlú Hala ati sí etí odò Habori tí ó wà ní agbègbè Gosani, ati sí àwọn ìlú Media.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun kẹsan Hoṣea, ni ọba Assiria kó Samaria, o si kó Israeli lọ si Assiria, o si fi wọn si Hala ati si Habori, leti odò Gosani, ati si ilu awọn ara Media.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹsàn-án ti Hóṣéà, ọba Áṣíríà mú Ṣamáríà ó sì kó Ísírẹ́lì lọ sí Áṣíríà. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hálà, ní Gósánì ní ọ̀dọ̀ Hábónì àti ní ìlú àwọn ará Médáì.