2 Kings 17:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli ṣe oríṣìíríṣìí nǹkan níkọ̀kọ̀, tí OLUWA Ọlọrun wọn kò fẹ́. Wọ́n kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sinu àwọn ìlú wọn: wọ́n kọ́ sinu ilé ìṣọ́, títí kan àwọn ìlú olódi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli si ṣe ohun ikọ̀kọ ti kò tọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kọ́ ibi giga fun ara wọn ni gbogbo ilu wọn, lati ile-iṣọ awọn olùṣọ titi de ilu olodi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun ìríra sí OLÚWA Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìsọ́ sí ìlú tí a dábòbò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.