2 Kings 18:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah ọba Juda si ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wipe, Mo ti ṣẹ̀; padà lẹhin mi: eyiti iwọ ba bù fun mi li emi o rù. Ọba Assiria si bù ọ̃dunrun talenti fadakà, ati ọgbọ̀n talenti wura fun Hesekiah ọba Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Heṣekáyà ọba Júdà rán oníṣẹ́ yìí sí ọba Áṣíríà ní Lákísì, “Mo ti mú ìṣe ohun tí kò dára kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba bu ọ̀ọ́dúnrún talẹ́ntì fàdákà àti ọgbọ̀n talẹ́ntì wúrà.