2 Kings 18:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sì ṣí wúrà tí ó wà lára ìlẹ̀kùn ilé OLUWA ati wúrà tí òun tìkararẹ̀ fi bo àwọn òpó ìlẹ̀kùn, ó kó wọn ranṣẹ sí Senakeribu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li akòko na ni Hesekiah ké gbogbo wura kuro lara awọn ilẹ̀kun ile Oluwa, ati kuro lara ọwọ̀n wọnni ti Hesekiah ọba Juda ti fi wura bò, o si fi wọn fun ọba Assiria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò yìí Heṣekáyà ọba Júdà ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé OLÚWA, kúrò àti ti òpó tí Heṣekáyà ọba Júdà ti gbéró ó sì fi fún ọba Ásíríà.