2 Kings 18:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Assiria si rán Tartani, ati Rabsarisi, ati Rabṣake, lati Lakiṣi lọ si ọdọ Hesekiah ọba pẹlu ogun nla si Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn si de Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn de, nwọn si duro leti idari omi abàta òke, ti mbẹ li eti òpopo pápa afọṣọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ásíríà rán alákòóṣo gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí ó pọ̀, láti Lákísì sí ọba Heṣekáyà ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n wá sí òkè Jérúsálẹ́mù wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá Alágbàfọ̀.