2 Kings 18:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkandinlọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Abi, ọmọ Sakaraya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Abi ọmọbinrin Sakariah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nígbà tí ó ti di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ A bì ọmọbìnrin Ṣakaríàyà.