2 Kings 18:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣé Ijipti ni ó gbójú lé pé yóo ran òun lọ́wọ́? Ó ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí ẹni tí ó ń fi igi tí kò ní agbára ṣe ọ̀pá ìtilẹ̀. Tí igi náà bá dá, yóo gún un lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ijipti rí sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, nisisiyi, iwọ gbẹkẹle ọ̀pa iyè fifọ yi, ani le Egipti, lara ẹniti bi ẹnikan ba fi ara tì, yio wọ̀ ọ li ọwọ lọ, yio si gun u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó Nísinsìn yìí ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Éjíbítì, ẹ̀rún igi pẹlẹbẹ ọ̀pá ìyè lórí ọ̀pá, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ọkùnrin tí ó sì pa á lára tí ó bá fi ara tìí Irú rẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.