2 Kings 18:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Eliakimu, ọmọ Hilikaya ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, bá àwa iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki nítorí pé a gbọ́. Má sọ èdè Heberu mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n wà lórí odi ń gbọ́ ohun tí ò ń sọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkiah, ati Ṣebna, ati Joa wi fun Rabṣake pe, Emi bẹ̀ ọ, ba awọn iranṣẹ rẹ sọ̀rọ li ède Siria; nitoriti awa gbọ́ ọ: ki o má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Juda li leti awọn enia ti mbẹ lori odi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Éláékímù ọmọ Hílíkíáyà, àti ṣébínà àti Jóà sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Ṣíríà, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Hébérù ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”