2 Kings 18:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati ọba nìkan ni ọba Asiria rán mi sí ni? Rárá, àwọn tí wọ́n wà lórí odi náà wà lára àwọn tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn náà yóo jẹ ìgbẹ́ ara wọn tí wọn yóo sì mu ìtọ̀ ara wọn bí ẹ̀yin náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Rabṣake sọ fun wọn pe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ, ati si ọ, lati sọ ọ̀rọ wọnyi bi? kò ṣepe awọn ọkunrin ti o joko lori odi li o rán mi si, ki nwọn ki o le jẹ igbẹ́ ara wọn, ati ki nwọn ki o le mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀ga mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sìí ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odo-ta ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”