2 Kings 18:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ má ṣe gbọ́ ti Hesekaya; nítorí pé ọba Asiria ní kí ẹ jáde wá kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia; òun yóo gbà yín láàyè láti máa jẹ èso àjàrà ninu ọgbà àjàrà yín. Ẹ óo máa jẹ èso orí igi ọ̀pọ̀tọ́ yín, ẹ óo sì máa mu omi láti inú kànga yín;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ máṣe fi eti si ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Fi ẹbùn wá oju rere mi, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá, ki olukuluku nyin ki o si mã jẹ ninu àjarà rẹ̀, ati olukuluku ninu igi ọ̀pọtọ rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si mu omi ninu àmu rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Má ṣe tẹ́tí sí Héṣékíáyà. Èyí ni ohun tí ọba Ásíríà sọ: ‘Ṣe àlàáfíà pẹ̀lú mi kí o sì jáde wá sí ọ̀dọ̀ sí mi.’ Nígbà náà olúkúlùkù yín yóò jẹun láti inú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́, yóò sì mumi láti inú àmù rẹ̀,