2 Kings 18:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà dákẹ́ jẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Hesekaya ti pàṣẹ fún wọn, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn enia pa ẹnu wọn mọ́, nwọn kò si da a li ohun ọ̀rọ kan: nitori aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a li ohùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ènìyàn náà dákẹ́ síbẹ̀ wọn kò sì sọ ohunkóhun, láti fi fèsì, nítorí ọba ti paláṣẹ, “Ẹ má ṣe dáa lóhùn.”