2 Kings 18:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wó gbogbo àwọn pẹpẹ oriṣa, ó wó gbogbo àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta ṣe, ó sì gé gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera. Ó rún ejò idẹ tí Mose ṣe, tí wọn ń pè ní Nehuṣitani nítorí pé títí di àkókò náà àwọn ọmọ Israẹli a máa sun turari sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú ibi gíga náà kúrò, ó sì fọ́ òkúta àwọn ère ó sì gé àwọn ère lulẹ̀ ó sì fọ́ ejò idẹ náà túútúú tí Móṣè ti ṣe, títí di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sun tùràrí sí. (Wọ́n sì pè é ní Néhúṣítanì.)