2 Kings 19:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Hesekaya ọba gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ, ó kà á. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé OLUWA, ó tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn onṣẹ na, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ sinu ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekíàyà gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún OLÚWA ó sì tẹ́ ẹ ṣíwájú OLÚWA.