2 Kings 19:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Heṣekáyà gbàdúrà sí OLÚWA: “OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ń gbé ní àárin àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.